Ẹ nlẹ, ọmọ Olomu apèran
Ọmọ ọrọ tii pani lẹsin jẹ
Asingba ni t’Omu
Ẹyin lọmọ bi ewúrẹ ba sọnu l’Omu
Ẹ ma mu lọ mi
Tani n se ẹgbẹ́ gbẹran-gbẹran?
Adìẹ Okoko lo sọnu l’Omu
Ẹ ma mu lọ mi
Tani n se ẹgbẹ́ gbẹyẹ-gbẹyẹ?
Àwa o gbewúrẹ, ao gbé àgùntàn
Ṣùgbọ́n ti obìnrin ba lẹdan lọrun
To ba sọnu l’Omu
To tadi rékeréke
To tadi rèkerèke
To hurun to fi de gbọngbọlọ ìtàn
Ẹ ma se ran ẹlẹsẹ wa pé mi ko ya
Ẹlẹsin ni kẹ rán wa
Nítorí ẹni gbé ni lobìnrin o fẹwọ,
Ẹni gbe ewúrẹ ati àgùntàn lo di igara
Níjọ́ ti ẹṣin ba sọnu l’Omu, ẹ sáré tètè de ile wa
Ẹyin lọmọ arọpọn jẹ òmítooro ẹṣin
Nígbà tí òmítooro dilẹ l’Omu nkọ?
Ní wọn ni ki gbogbo ọmọ Osu mọ lamítooro
Ómu sẹ, gbọngi kan
Ọmọ abẹ aka ni ejò sún
Abẹ aka ni ejò sún, abẹ ọrọ̀ ni ẹmọn gbéjẹ
Ọmọ gba-n-yẹkẹ
Gba-n-yẹkẹ gba-n-yẹkẹ
Ewúrẹ ilé ko gbọdọ gba-n-yẹkẹ lójú onisẹ
To gba-n-yẹkẹ, oníṣẹ baba wọn ni mu wọn jẹ
E nlẹ o
Ọmọ Ómu Àrán nílé Olomu apèran
Nílé okanlelọgọta ẹ̀kọ́
Sísán logun, wíwàmu lọgbọn
Ọkànla tó kú ló lọ ilé Olomu apèran.
Ọmọ ọrọ tii pani lẹsin jẹ,
Nígbà ti o di àjíǹ,
Mo gbọ pápápi láàrin òde,
Mo ba so mọ yeye létí aṣọ
Mo ni mo n gbọ papapi laarin òde
Iya ni kín dakẹ,
Kin lọ rèé sin mẹdọ
Iya ni kín dakẹ, pe àlejò kii sobéèrè
Ìgbàti o di afẹ́mójúmọ,
Iya wẹ mi, o pa mi ròkiroki
O n pa mi lọ lọmọ sẹ lára
Mo ni, “iya, ẹ jẹ ki a lọ wo oun ti n se pápápi laarin òde”
Awa buse gada
O di ẹhinkule Olomu apèran
A de ẹhinkule Olomu apèran
Nibẹ la ti ba ìyàn, ti ìyàn n fa odi lára
Iyán lo lọ́wọ́, ìyàn ko lẹsẹ, ìyàn n gùn’gi lérèkó
Igun lakọ̀le igun ńlá,
Igun tóbi lẹyẹ